
Kí ni ó fà ọ́ láti darapọ̀ mọ́ DOAB gẹ́gẹ́ bí aṣoju?
Ìwúrí mi láti darapọ̀ mọ́ DOAB gẹ́gẹ́ bí aṣojú in Nigeria wá láti inú ìjìbára mi pẹ̀lú pẹpẹ DOAB fún ìgbà pípẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùṣètò-ìwé ni ile-ìkàwé tí mo tiń ṣiṣẹ́; Mo ti ṣe ìtọ́kasí àwọn olùlò wa àti àwọn ile-ìkàwé mìíràn sí àwọn ìwé ìtàkùrọ̀sí lórí DOAB. Èyí ni ọ̀nà mi láti san ìrànlọ́wọ́ tí DOAB fún ilé-ìkàwé mi síwájú.
Bákan náà, gẹ́gẹ́ bí akọ́wé ilé-ìkàwé atìlẹyìn ìwádìí àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ìwọlésí ọ̀fẹ́, mo ṣàkíyèsí pé ìfarahàn àwọn ìwé àti àkọsílẹ̀ tí a tẹ̀jáde ní Orílẹ̀-èdè wà nínú ètò ìmọ̀ àgbáyé kò pọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtẹ̀jáde ìwé fún ìgbésókè ni ìlé-éko pọ̀. Gẹ́gẹ́ bí pèpé àgbáyé, DOAB bá ìpinnu mi mu déédé láti mu ìwárí àti àtúnlò ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ Áfríkà ní ìlọsíwájú. Gẹ́gẹ́ bí aṣojú DOAB, mo lè mú ìpinnu yìí ṣẹ.
Báwo ni o ṣe ń gbero láti ṣe agbega ìtẹ̀jáde ìwé tí gbogbo ènìyàn lè wọlé sí ní orílẹ̀-èdè rẹ/tabi agbègbè rẹ nípasẹ̀ iṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣoju DOAB?
Ìdojúkọ mi yóò wà lórí àwọn agbègbè méjì tí ó sopọ̀ mọ́ ara wọn – ìkọ́ni àgbára àti ìlànà ìdásílẹ̀.
Mo gbèrò láti bá àwọn akọ̀wéilé-ìkàwé, àwọn ilé-ìtẹ̀wé yunifásítì, àti àwọn olóòtú ṣiṣẹ́ nipasẹ̀ àwọn nẹ́tíwọ́ọ̀kì ọjọ̀gbọ́n àti àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ láti mú kí òye ìlànà ìtẹ̀jáde ìwé OA àti àwọn ọ̀nà ìwárìí dára sí.
Ní àpá ìlànà ìdásílẹ̀, èmi yóò ṣe ìgbìmọ̀ fún ìdàpọ̀ tí ó dára jù láàrin àwọn àkójọpọ̀ ilé-ẹ̀kọ́, àwọn ìgbésẹ̀ ìtẹ̀jáde ìbílẹ̀, àti àwọn pẹpẹ ìwárìí àgbáyé bíi DOAB, láti rí dájú pé àwọn ìwé ìràhùn-ọ̀fẹ́ Nàìjíríà kìí ṣe tí wọ́n tẹ̀ jáde nìkan ṣùgbọ́n pé wọ́n ṣí hàn lọ́pọ̀lọpọ̀ àti pé a lè tún wọn lò. Ní àfikún, èmi yóò ṣe ìgbìmọ̀ fún ìfisílẹ̀ àwọn ìwé ìràhùn-ọ̀fẹ́ sínú àwọn ìjíròrò lórí àtúnṣe ìdíwọ̀n ìwádìí.
Kí ni tàbí ta ló ń fún ọ ní ìmísí nínú ipa rẹ?
Ní ìbẹ̀rẹ̀, ìmúlò ìṣọ̀kan àti ìtẹ̀síwájú nínú ìfọwọ́sowọpọ̀ láti mú kí gbogbo ènìyàn ní àǹfààní sí àwọn ohun èlò ẹ̀kọ́ ní Nàìjíríà. Ẹ kú ìyìn púpọ̀ sí àwọn olùkọ́ ilé-ìkàwé, àwọn olóòtú, àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́-òjògbọ́n tí ń jẹ́ kí àtẹ̀jáde ìmọ̀ ṣí sílẹ̀, tí ìjọba àwùjọ sì ń darí, máa bá a lọ káàkiri ayé láìka àwọn ìṣòro tó wà.
Mo tún ní ìmísí láti inú iṣẹ́ tí LIBSENSE ń ṣe níbi ìbáṣepọ̀ agbára, ìlànà, àti amáyédẹrùn tí àwùjọ ń darí fún ìmọ̀ ṣí sílẹ̀ àti sáyẹ́ǹsì ní Ìwọ̀-Oòrùn Áfíríkà. DOAB ń fi díẹ̀ nínú àwọn ìlànà wọ̀nyí hàn ní ìṣe gidi, ìfarahàn yìí sì jẹ́ orísun ìmísí tó lágbára fún iṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí aṣojú DOAB.
Àwọn ìṣòro tó tóbi jùlọ wo ni o rí ní ìtẹ̀síwájú ìtẹ̀jáde ìwé tí gbogbo ènìyàn lè wọlé sí ní orílẹ̀-èdè rẹ/tabi agbègbè rẹ?
Àwọn ìṣòro tí mo rí ni àìní agbára nípa àwọn ìlànà ìtẹ̀jáde, amáyédẹrùn, àti àwọn àpẹẹrẹ ìṣúná tí ó lè yáyà.